HOSEA 2:6 -13
(Ese.6– 7) – Se afayo Igbese idajo ti Olorun gbe ti Gomeri (Iyawo to
sagbere lo).
- Kiyesi, emi o fi egun sagbara yii ona re ka.
- Emi o si mo odi, ti oun ki yoo fi ri ona re mo.
- Oun o si lepa awon ayanfe re, ki yoo le ba won.
- Oun yoo si wa won, ki yoo ri won (awon to ba sagbere lo.).
- Nigbana yoo wipe, Oun o pada to oko re isaaju lo
- Nitori ti o san fun un, nigba naa ju ti isisiyi lo.
(Ese. 8 – 9) – Se afayo asiri igbese idajo Olorun ti O gbe ti Gomeri.
- Oun ko i tii mo pe Olorun ni eniti o fun un ni oka, oti waini titun ati Ororo.
- Olorun ni eniti o mu fadaka ati wura re po sii, ti won fi se baali.
- Olorun yoo pada mu oka re kuro ni akoko re ati oti waini ni igba re.
- Olorun yoo gba irun aguntan ati ogbo Re pada ti O fi bo ihoho re.
(Ese. 10 – 13) – Se afayo abajade / ohun ti idajo Olorun yoo mu ba
Gomeri.
- Ni isisinyi ni emi o si itiju re sile loju awon ayanfe re, enikeni ki yoo si gbaa.
- Olorun yoo fi opin si gbogbo ayo re, ojo ase re, osu titun ati ojo isinmi re, gbogbo owo re.
- Olorun yoo pa ajara re ati igi opoto re run.
- Olorun yoo so won di igbo awon eranko igbe yoo si je won.
- Olorun yoo be oju baali wo lara re nibiti o gbe fi turari jona fun won.
- Oruka eti, ohun oso re ti o fi to awon ayanfe re leyin ti o fi gbagbe Oluwa – yoo dibaje.
Akiyesi.
- Olorun fi ife Re alailegbe fe awon Omo Israeli bee gege ni O si fe awa naa loni nitori ohun ni o wa (Orin Dafidi 24:1; Johanu 3:16; Matt. 5:45).
- Bi Olorun ti fe wa to yii, ohun ti o korira ni ese, okan ninu iwa ti o le mu wa da ese kiakia ni aeni Iberu olorun lokan wa. Nipa bee kii pe ti a fi yago kuro lodo Olorun, eniti o fe wa nipa aeni emi iberu wa.
- Ohun gbogbo ti a ni lo fun igbaye gbadun wa ni Olorun ti da siwaju awa eniyan. Sibesibe awon irorun wonyii ni a n si lo, ti asilo yii si n mu wa jina si Olorun ti O le mu ki o binu si wa.
- Eko yii n laaye wa wipe, dipo ti a ba fi igbaye gbadun wa sin Olorun ki o le tun bo ma po sii, n se ni a fi n mu Olorun binu (Vs. 12 – 13), eyiti ko ye ki o ri bee