(Jakobu 1: 12) Ese Atenumo
Ki bukun wa lodun yii le di pupo, a nilo lati se won nkan wonyii bi Akiyesi ati bii iranni leti -:
Vs. 4 – 5 Anilo Suuru; jije Pipe ati ailabubuku; nini Ogbon Olorun ati Igbagbo
V. 17. Nitori wipe gbogbo ebun rere ati pipe n ti odo Baba imole wa lodo Re, ko le si iyipada.
V. 27 Ti a ba di eni Ibukun yii tan Ijosin wa gbodo je Mimo ati aileeri niwaju Olorun Baba.
Bi ara re ni ibeere wonyii, lakoko idanwo, bawo ni suuru ati itara mi se ri (si ara mi ati si elomiran). Iru ogbon wo ni mo n lo,(ti Olorun tabi ti eniyan). Nigbati a bori isoro tabi iponju bee tan, iru iha wo la ko da Olorun ninu ise Isin wa.
(Jakobu 2:13) Ese Atenumo
Ki Ibukun wa lodun yii le di pupo, ki o le maa ni idena tabi dibaje mo wa lowo, a nilo lati se awon nkan
wonyii bi Akiyesi ati bi iran –ni leti
Vs. 2 – 4 Kinni yoo je isesi wa ati ojuse wa lawujo ti a ba ba ara wa. Ti Okunrin kan ba wa si ipejopo wa pelu Oruka ati aso daradara, ti talaka kan si wa pelu ninu aso gbigbo. Ti eyin si bu iyin fun eniti o wo aso daradara. Eyin ko ha n da ara yin si meje laarin ara yin, ti e si di Onidajo ti o ni ero buburu.
V. 9 Sugbon bi eyin ba n se ojusaaju eniyan eyin n dese a si n da yin lebi nipa ofin bi arufin.
V. 13 Nitori eniti ko saanu, ni a o se idajo fun laesi aanu; Sugbon aanu n sogo lori idajo.
Bere lowo ara re, sise idajo elomiran ni n ma po ni tabi ifi ara eni si ipo onitohun ki o to soro ni a ma n
po? Ki Oluwa fi emi Re ran wa lowo lati ma ma se idajo ati ojusaaju awon elomiran.
(Jakobu 3:8) Ese Atenumo
Ki ohun ti Jakobu n so ninu ese yii le ye wa daada, o ye ki a ka (Matteu 12:37 – 37). Ki Ibukun wa le e di pupo, ki o si ma ni idana tabi idibaje mo wa lowo, nipa lilo ahon wa, a nilo lati kiyesisara gan –an
V. 2 Nitori ninu ohun pupo ni gbogbo wa n sise. Bi enikeni ko bas ise ninu oro, oun naa ni eni pipe, Oun ni o si le ko gbogbo ara ijanu.
V.6 Ina si ni ahon, aye se si nii laarin awon eya ara wa, ni ahon ti n ba gbogbo ara je ti o si n tinabo ipa aye wa; Orun apaadi si ntinabo oun naa.
V. 8 Sugbon ahon ni enikeni ko le tu loju; ohun buburu alaigboran ni, o kun oro Iku ti n pani.
Dahun awon ibere yii sinu ara re:-
Nje enu / ahon ti a fi n yin Oluwa, se a ko tun fi ma bu eniyan.
Nje enu/ ahon wa n gba ijanu bi o ti ye.
Nje Olorun le gbe okan Re le wa nipa oro enu wa.
E jeki a se afayo koko adura wa lati inu ese (V 17.)
1. Oluwa, ki Ibukun mi le di pupo lodun yii, fun mi ni ogbon ti o mo, ti yoo mo ohun ti oye ki n se lati so Ibukun mi di pupo.
2. Oluwa, ran mi lowo lati le wa ni alaafia pelu gbogbo eniyan. Bi mo si ti n se eyi, bi enikeni ko ba gba
Alaafia laaye pelu mi, ran mi lowo lati mo bi mo se le duro ninu Re.
3. Nigba gbogbo, mase jeki Satani so mi di eniti yoo ma mu ki nkan diju tabi le fun elomiran loruko Jesu.
4. Se mi ni alaanu ki emi naa si ma ri aanu Re gba nigba gbogbo loruko Jesu.
5. Eso rere ni ki o je ki n so loruko Jesu.
6. Gba mi lowo emi iyemeji ati agabagebe ni iyooku aye mi loruko Jesu
7. Odun 2913 jeki o dara fun mi ju ateyinwa lo loruko Jesu.
No comments:
Post a Comment