Saturday, June 22, 2013

IGBALA ISRAELI SI ILEKUN FUN GBOGBO AYE

Bibeli Kika (Romu 11: 11 – 24)

(Vs 11 - 13). – Se afayo bi aelakasi Omo Israeli tise silekun fun gbogbo eniyan.
1. Aegboran (Isubu) Israeli mu Igbala to awon keferi, ki Olorun le fi won jowu – V. 11;
John 1:11 – 12.
2. Aegboran (Isubu) Israeli mu ki awon keferi di oloro – V. 12
3. Aegboran (Isubu) Israeli mu ki keferi di eniti n ba Olorun soro nipase Paulu – V. 13;
Gal 4:7
(Vs 14- 17). – Se afayo, bi ilekun IGBALA se di  ti gbogbo aye.
1. Israeli ni Olorun fe mu jowu ni Ibere pepe – V. 14
2. Israeli ta ife Olorun nu, eyi si ilekun ilaja sile fun awon Keferi - V. 15; II
Cor. 5:17 – 20.
3. Israeli je gbongbo, Awon Keferi wa di eka re – v. 16a
4. Bi gbongbo ba je Mimo, Keferi naa (ti o je eka) yoo je mimo pelu. – V. 16b.
5. Bi eka igi Olifi igbe ti n je adun, bee ni eka re naa yoo maa je adun  - V. 17
(Vs. 18 – 20) – Se afayo igbese ti o le mu IDIGBOLU ba igbala naa.
1. Igbakigba ti eka bar o wipe oun le da duro – V. 18
2. igbakigba ti eka ko ba tete ri omi fun imudagba re. – V 19.
3. Igbakigba ti  igbagbo eka ko ba duro mo – V. 20
(Vs. 21 - 24) – Se afayo ERE IGBALA ti a silekun re sile fun gbogbo aye.
1. Abo wa ninu Igbala naa – V 21
2. Oore wa ninu Igbala naa – V 22
3. Iso di titun wa ninu Igbala naa – V 23
4. Wiwa lalaafia (Ninu agbara nigba gbogbo) wa ninu Igbala naa – V. 24
AKIYESI.
1. (Romu 9:25 – 26) Olorun je Eniti n se ohun – ko – hun ti o wu U. Ko si enikeni ninu eniyan
ti o le yee lowo Re wo
2. Alaanu julo ni Olorun (Romu 9:15, 18), eniti O ba wu Olorun ni n sanu fun. Nitori naa ti a ba
ri aanu Re gba, O ye ki a lo aanu re bi o ti to ati bi o ti ye
3. Nikete ti Olorun ba ti ri wipe a ko lo aanu Oun bi o ti dara, O see se ki o gba kuro lowo wa ki
O si fi fun elomiran.
AKOKO ADURA.
1. Mase jeki n si aanu Re lo lori aye mi
2. Gbogbo agbara ti mu ki a si aanu Olorun lo bi Samsoni ati Judasi, ko segbe lori aye mi ati
idile mi.
3. Imisi ohun elo Emi Mimo  ko ma gbodo  dagbere lori aye mi.
4. Ipo mi ni ite ogo ko gbodo sofo.
5. Mu mi lajo aye mi ja fun rere o.

No comments:

Post a Comment