Bibeli Kika (Romu 11: 25 – 36)
(Ese 25 - 27). – Se afayo alaye die ti o fi otito nipa Igbala Israeli han.
- Paulu ko fe ki awon ara Romu wa ni okunkun si otito nipa Igbala awon omo Israeli – V 25
- Paulu ko fe ki awon ara Romu ro wipe awon nikan ni Olorun seto Igbala Re fun – V. 25
- Olorun ti se ipinu Re pe lati Sioni ni Igbala yoo ti jade wa si gbogbo eniyan – V. 26
- Olorun ti ba won da majemu Re lati dari ese won ji won, tabi mu se won kuro – V. 27
(Ese 28 – 29). – Se afayo AGBEKALE bi
Olorun se gba Israeli la.
- Nipase awon baba won Olorun ti so won di ayanfe, ki I se nipa se itankale Ihinrere. V. 28.
- Olorun nawo ipe Re ti ko yipada si won lati fi pe won (Majemu ayeraye) – V. 29.
(Ese. 30 - 32) – Se afayo IYATO
bi Igbala ti awon ara Romu si ti Israeli.
- Nipa aanu Olorun ni awon ara romu fi ri Igbala gba (nipa itankalae ihinrere). – V. 30
- Bi awon Israeli ba tile je alaegboran, aanu Olorun si duro fun won – V 31.
- Awon ara Romu je alaegboran Sugbon a fi aanu Olorun gba won la – V 32.
(Ese. 33 – 36) – Se afayo TITOBI
OLORUN ti O fi gbanila, ti o ye fun Iyin ati Ogo.
- Titobi Olorun je awamaridi o kun fun oro ijinle ati ogbon – V. 33
- Titobi Olorun ko nilo imoran awa eniyan ki O to lo titobi Re. – v. 34
- Titobi Olorun ko nilo iranlowo awa eniyan ki O to fi titobi Re joba. V. 34.
- Lati inu titobi Olorun n I ipa ati agbara fun ohun gbogbo ti n wa – V. 36.
- Ti Olorun ni ogo ati iyin wa fun lae ati lae lae. Ko si afiwe Re.
AKIYESI.
- Asiri bi Olorun se je Olorun, ko fi han eniyan. Eniyan ko si le mo o titi lae lae.
- Bi a ba gba eniyan la kuro ninu ese re, aanu Olorun lo ri gba, ki i se eto re. Ki iru eni bee mo wipe Oun nikan ko ni aanu yi wa fun. Aanu Olorun wa fun gbogbo eniyan ti o ba gbagbo (Rom 10:11-12; Gala. 3:28; Ise Awon Aposteli 10:36)
- Bi Olorun ba wo wa se laanu, o di ojuse ti awa naa lati ma jeki aanu Re bo sonu kuro lowo wa(I Peteru 5:8 – 11) Bi Olorun ba gba wa la, Ihinrere Igbala naa di ise wa lati tan – an de odo awon alaegbagbo (Ise Awon Aposteli 1:8; 4:12; II Korinti 5:17 – 20)
No comments:
Post a Comment