Showing posts with label Yoruba Message. Show all posts
Showing posts with label Yoruba Message. Show all posts

Monday, July 7, 2014

ASIRI OTITO NIPA IGBALA AWON OMO ISRAELI



Bibeli Kika  (Romu 11: 25 – 36)    
   

(Ese 25 - 27). – Se afayo alaye die ti o fi otito nipa Igbala Israeli han.
  1. Paulu ko fe ki awon ara Romu wa ni okunkun si otito nipa Igbala awon omo Israeli – V 25
  2. Paulu ko fe ki awon ara Romu ro wipe awon nikan ni Olorun seto Igbala Re fun – V. 25
  3. Olorun ti se ipinu Re pe lati Sioni ni Igbala yoo ti jade wa si gbogbo eniyan – V. 26
  4. Olorun ti ba won da majemu Re lati dari ese won ji won, tabi mu se won kuro – V. 27

(Ese 28 – 29). – Se afayo AGBEKALE bi Olorun se gba Israeli la.
  1. Nipase awon baba won Olorun ti so won di ayanfe, ki I se nipa se itankale Ihinrere. V. 28.
  2. Olorun nawo ipe Re ti ko yipada si won lati fi pe won (Majemu ayeraye) – V. 29.

(Ese. 30 - 32)Se afayo IYATO bi Igbala ti awon ara Romu si ti Israeli.
  1. Nipa aanu Olorun ni awon ara romu fi ri Igbala gba (nipa itankalae ihinrere). – V. 30
  2. Bi awon Israeli ba tile je alaegboran, aanu Olorun si duro fun won – V 31.
  3. Awon ara Romu je alaegboran Sugbon a fi aanu Olorun gba won la – V 32.

(Ese. 33 – 36)Se afayo TITOBI OLORUN ti O fi gbanila, ti o ye fun Iyin ati Ogo.
  1. Titobi Olorun je awamaridi o kun fun oro ijinle ati ogbon – V. 33
  2. Titobi Olorun ko nilo imoran awa eniyan ki O to lo titobi Re. – v. 34
  3. Titobi Olorun ko nilo iranlowo awa eniyan ki O to fi titobi Re joba. V. 34.
  4. Lati inu titobi Olorun n I ipa ati agbara fun ohun gbogbo ti n wa – V. 36.
  5. Ti Olorun ni ogo ati iyin wa fun lae ati lae lae. Ko si afiwe Re.
AKIYESI.
  1. Asiri bi Olorun se je Olorun, ko fi han eniyan. Eniyan ko si le mo o titi lae lae.
  2. Bi a ba gba eniyan la kuro ninu ese re, aanu Olorun lo ri gba, ki i se eto re. Ki iru eni bee mo wipe Oun nikan ko ni aanu yi wa fun. Aanu Olorun wa fun gbogbo eniyan ti o ba gbagbo (Rom 10:11-12; Gala. 3:28; Ise Awon Aposteli 10:36)
  3. Bi Olorun ba wo wa se laanu, o di ojuse ti awa naa lati ma jeki aanu Re bo sonu kuro lowo wa(I Peteru 5:8 – 11) Bi Olorun ba gba wa la, Ihinrere Igbala naa di ise wa lati tan – an de odo awon alaegbagbo (Ise Awon Aposteli 1:8; 4:12; II Korinti 5:17 – 20)

Friday, July 4, 2014

IWA ATI ISE: AMUYE AYE KRISTIANI



Bibeli kika-: (Jakobu 1:19).
Ifaara:         Ti ko ba si iwa ati ise, nje a le mo eniti o fewa tabi ti a wa naa feran.
(Vs. 19 – 20) – Se afayo awon ona ti a le gba lo iwa ati ise wa tabi ti iwa ati ise wa le fi wa han bi ati se je.
1.      Nipa bi a ba ti se gbo oro ati bi a ba se dahun si oro ti a gbo.
2.      Nipsa bi a ba se lora tabi yara lati binu si.
3.      Nitori ibinu eniyan ki i sise ododo Olorun.
(Vs. 21 – 22) – Nipa awon ona wo l le fi iwa ati ise wa jo kristiani.
1.      Nipa fifi gbogboeeri ati buburu  aseleke lele ni apa kan.
2.      Nipa fifi okan tutu gba oro naa ti a gbin ti o le gba okan la
3.      Nipa jije Oluso oro naa, kii se olugbo nikan, ki a maa tan ara wa je.
(Vs 23 – 24) – Se afayo apejuwe eniti Iwa ati ise re yato si oro naa ti o gbo.
1.      O dabi okunrin ti o sakiyesi oju ara re ninu awojiji.
2.      Loju kan naa o si gbagbe bi oun ti ri, o n ba tire lo.
(Vs 25 – 27) – Se afayo eniti o fi Iwa ati Ise re jo Kristiani bi oro naa ti o gbo.
1.      Iru eni bee yoo ma woo inu ofin pipe, ofin ominara ti yoo si duro ninu re.
2.      Iru eni bee ki se olugbo ti o gbagbe, bikose oluse ise oro naa.
3.      Iru eni bee yoo di alabukun fun ninu ise re.
4.      Iru eni bee yoo le ko ilo ahon re niijanu ninu isin re si Olorun.
5.      Iru eni bee yoo le sin Olorun ni mimo bi Olorun ti n fe.
6.      Iru eni bee yoo le mo bi aati bojuto awon alaeni gbogbo
7.      Iru eni bee yoo le pa ara re mo laelabawon.
Akiyesi.
  1. Ati eniti o je Omoleyin Kristi ati eniti ki i se e, Iwa ati Ise wa je ona ti a n fi n pew a ni eniyan, Mejeeji
yii la si le fi mo odiwon ife tabi ikorira wa si elomiran.
  1. Omoeyin Kristi gbodo wa jeki iwa ati ise oun je dara dara si gbogbo eniyan. Eyi ni yoo si ran ise ijeri ihinrere lowo (Matteu 5:43 – 48; Romu 12: 16 – 18).
  2. Bi awon aladugbo wa ba tile n ba wa wa wahala, iwa ati ise wa (bi Omoeyin Kristi) gbodo so fun won pe awa ko ni n won n se e si bikose si Olorun, Eniti o kun oju osuwon lati gba ija wa ja, ti yoo gba ejo wa wi (Eksodu 14:18, 25)
  3. Ninu ijakadi aye, iwa ati ise wa gbodo fi wa han bi Omoeyin Kristi.
Akoko Adura.
  1. Jeki agbara imole Re maa se amona mi nigba gbogbo.
  2. Womi lagbara ti o to ti n go fi le si O titi opine mi mi loruko Jesu.
  3. Bi aye n gbogun, ti esu si n dode, nitori ti mo gba O gbo. Ma fi mi le esu lowo o.
  4. Oluwa, jeki odun yii je aluyo fun rere aye mi ati Idile mi
Oore – ofe Ifarada ti yori si ayo ati inu didun ninu Re Oluwa fi fun mi

Wednesday, February 19, 2014

OGBON ATI OMUGO JE ASAN


 Oniwaasu 2: 12 – 16
Orin:               (YHB 291) – A! mba le legberun ahon.
Adura:            Olorun Eleda ati Oloore mi, ngo mo bi nba ti yin O to? Mo dupe o.
Ifaara:            Ninu Ogbon ati Omugo, ewo lo ye ki eniyan ni?. 

(Ese. 12) – Se afayo bi Solomoni Oba ti ro ninu okan re nipa jije ologbon tabi omugo.
1.      Mo si yi ara mi pada lati wo ogbon ati ise omugo.
2.      Nitoripe kinni Okunrin naa ti nbo leyin oba yoo le se?
3.      A fi eyi ti a ti se tan ni yoo se.

(Ese. 13 – 14) – Se afayo iyato ti Solomoni oba afayo ninu ogbon ati omugo.
1.      Nigba naa ni mo ri pe ogbon ta were (Omugo) yo bi imole ti ta okunkun yo.
2.      Oju ologbon n be ni ori re, Sugbon omugo n rin ni okunkun.
3.      Emi si mo wipe abayori kanna ni gbogbo won.

(Ese. 15 – 16) – Se afayo awon ohun ti yoo pari Ologbon ati Omugo bi Solomoni ti rii.
1.      Nigba naa ni mo wi ni aya mi pe.
2.      Bi o ti n se asiwere (Omugo), bee ni n se si emi tikalara mi
3.      Nitori kinni emi se gbon ju? nigba naa ni mo wi ni okna mi pe assan ni eyi pelu
4.      Nitoripe iranti ko si fun ologbon pelu omugo laelae
5.      Ki a wo o pe bi akoko ti koja, bee ni ojo ti n bo
6.      A o gbagbe gbogbo re, ologbom ha se n ku bi i omugo.

Akiyesi.
  1. Ogbon ti ko ba ni iberu Olorun ninu je ti eniyanati aye. Iru ogbon bee a si maa pa ologbon lara. (Orin
Dafidi 111:10)
  1. Ogbon n ko ipa ti o po ninu aye eniyan
Ø  Ogbon ni a fi n kole (Owe 24:3).
Ø  Ogbon sanju agbara lo, (Oniwaasu 9:16).
Ø  Ogbon ni a fi n soro lawujo (Owe 31:26).
Ø  Ogbon ati io wonu ara won (Jakobu 3:13).
  1. Ati Ogbon ati Omugo, bi a ti bi won sinu aye, bee ni iku yoo tun mu won lo (Oniwaasu 2:16)

Akoko Adura.
  1. Loruko Jesu, OLUWA mi, fun mi ni emi ogbon ti yoo ni iberu Re lokan bii ti Josefu ati Danieli.
  2. Loruko Jesu, OLUWA mi, awon akonilogbon jona ko gbodo ri mi gbese lojo aye mi.
  3. Ran mi lowo fun awon Omo ti o fi fun mi to ni emi ogbon ti yoo mi enikookan won tayo ni rere loruko Jesu.
  4. “Ologbon laye, ko ni sinmi, beeni Omugo eniyan ko ri aye wa” OLUWA mi, fun mi ni ogbon ti o ni isinmi ati suuru, ki n le wulo fun Ogo ati Ola Re loruko Jesu.
Tile – tile mi, OLUWA, jeki a ba egbe pe.