Showing posts with label oniwasu. Show all posts
Showing posts with label oniwasu. Show all posts

Monday, July 7, 2014

ASIRI OTITO NIPA IGBALA AWON OMO ISRAELI



Bibeli Kika  (Romu 11: 25 – 36)    
   

(Ese 25 - 27). – Se afayo alaye die ti o fi otito nipa Igbala Israeli han.
  1. Paulu ko fe ki awon ara Romu wa ni okunkun si otito nipa Igbala awon omo Israeli – V 25
  2. Paulu ko fe ki awon ara Romu ro wipe awon nikan ni Olorun seto Igbala Re fun – V. 25
  3. Olorun ti se ipinu Re pe lati Sioni ni Igbala yoo ti jade wa si gbogbo eniyan – V. 26
  4. Olorun ti ba won da majemu Re lati dari ese won ji won, tabi mu se won kuro – V. 27

(Ese 28 – 29). – Se afayo AGBEKALE bi Olorun se gba Israeli la.
  1. Nipase awon baba won Olorun ti so won di ayanfe, ki I se nipa se itankale Ihinrere. V. 28.
  2. Olorun nawo ipe Re ti ko yipada si won lati fi pe won (Majemu ayeraye) – V. 29.

(Ese. 30 - 32)Se afayo IYATO bi Igbala ti awon ara Romu si ti Israeli.
  1. Nipa aanu Olorun ni awon ara romu fi ri Igbala gba (nipa itankalae ihinrere). – V. 30
  2. Bi awon Israeli ba tile je alaegboran, aanu Olorun si duro fun won – V 31.
  3. Awon ara Romu je alaegboran Sugbon a fi aanu Olorun gba won la – V 32.

(Ese. 33 – 36)Se afayo TITOBI OLORUN ti O fi gbanila, ti o ye fun Iyin ati Ogo.
  1. Titobi Olorun je awamaridi o kun fun oro ijinle ati ogbon – V. 33
  2. Titobi Olorun ko nilo imoran awa eniyan ki O to lo titobi Re. – v. 34
  3. Titobi Olorun ko nilo iranlowo awa eniyan ki O to fi titobi Re joba. V. 34.
  4. Lati inu titobi Olorun n I ipa ati agbara fun ohun gbogbo ti n wa – V. 36.
  5. Ti Olorun ni ogo ati iyin wa fun lae ati lae lae. Ko si afiwe Re.
AKIYESI.
  1. Asiri bi Olorun se je Olorun, ko fi han eniyan. Eniyan ko si le mo o titi lae lae.
  2. Bi a ba gba eniyan la kuro ninu ese re, aanu Olorun lo ri gba, ki i se eto re. Ki iru eni bee mo wipe Oun nikan ko ni aanu yi wa fun. Aanu Olorun wa fun gbogbo eniyan ti o ba gbagbo (Rom 10:11-12; Gala. 3:28; Ise Awon Aposteli 10:36)
  3. Bi Olorun ba wo wa se laanu, o di ojuse ti awa naa lati ma jeki aanu Re bo sonu kuro lowo wa(I Peteru 5:8 – 11) Bi Olorun ba gba wa la, Ihinrere Igbala naa di ise wa lati tan – an de odo awon alaegbagbo (Ise Awon Aposteli 1:8; 4:12; II Korinti 5:17 – 20)

Wednesday, February 19, 2014

OGBON ATI OMUGO JE ASAN


 Oniwaasu 2: 12 – 16
Orin:               (YHB 291) – A! mba le legberun ahon.
Adura:            Olorun Eleda ati Oloore mi, ngo mo bi nba ti yin O to? Mo dupe o.
Ifaara:            Ninu Ogbon ati Omugo, ewo lo ye ki eniyan ni?. 

(Ese. 12) – Se afayo bi Solomoni Oba ti ro ninu okan re nipa jije ologbon tabi omugo.
1.      Mo si yi ara mi pada lati wo ogbon ati ise omugo.
2.      Nitoripe kinni Okunrin naa ti nbo leyin oba yoo le se?
3.      A fi eyi ti a ti se tan ni yoo se.

(Ese. 13 – 14) – Se afayo iyato ti Solomoni oba afayo ninu ogbon ati omugo.
1.      Nigba naa ni mo ri pe ogbon ta were (Omugo) yo bi imole ti ta okunkun yo.
2.      Oju ologbon n be ni ori re, Sugbon omugo n rin ni okunkun.
3.      Emi si mo wipe abayori kanna ni gbogbo won.

(Ese. 15 – 16) – Se afayo awon ohun ti yoo pari Ologbon ati Omugo bi Solomoni ti rii.
1.      Nigba naa ni mo wi ni aya mi pe.
2.      Bi o ti n se asiwere (Omugo), bee ni n se si emi tikalara mi
3.      Nitori kinni emi se gbon ju? nigba naa ni mo wi ni okna mi pe assan ni eyi pelu
4.      Nitoripe iranti ko si fun ologbon pelu omugo laelae
5.      Ki a wo o pe bi akoko ti koja, bee ni ojo ti n bo
6.      A o gbagbe gbogbo re, ologbom ha se n ku bi i omugo.

Akiyesi.
  1. Ogbon ti ko ba ni iberu Olorun ninu je ti eniyanati aye. Iru ogbon bee a si maa pa ologbon lara. (Orin
Dafidi 111:10)
  1. Ogbon n ko ipa ti o po ninu aye eniyan
Ø  Ogbon ni a fi n kole (Owe 24:3).
Ø  Ogbon sanju agbara lo, (Oniwaasu 9:16).
Ø  Ogbon ni a fi n soro lawujo (Owe 31:26).
Ø  Ogbon ati io wonu ara won (Jakobu 3:13).
  1. Ati Ogbon ati Omugo, bi a ti bi won sinu aye, bee ni iku yoo tun mu won lo (Oniwaasu 2:16)

Akoko Adura.
  1. Loruko Jesu, OLUWA mi, fun mi ni emi ogbon ti yoo ni iberu Re lokan bii ti Josefu ati Danieli.
  2. Loruko Jesu, OLUWA mi, awon akonilogbon jona ko gbodo ri mi gbese lojo aye mi.
  3. Ran mi lowo fun awon Omo ti o fi fun mi to ni emi ogbon ti yoo mi enikookan won tayo ni rere loruko Jesu.
  4. “Ologbon laye, ko ni sinmi, beeni Omugo eniyan ko ri aye wa” OLUWA mi, fun mi ni ogbon ti o ni isinmi ati suuru, ki n le wulo fun Ogo ati Ola Re loruko Jesu.
Tile – tile mi, OLUWA, jeki a ba egbe pe.